Native Bible

2 Kings 5:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀tẹ̀ Naamani yóò lẹ̀ mọ́ ọ àti sí irú-ọmọ rẹ títí láé.” Nígbà náà Gehasi kúrò níwájú Eliṣa, ó sì di adẹ́tẹ̀, ó sì funfun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.

2 Kings 5:27 in English

2 Kings 5:27 · Berean Standard Bible

Therefore, the leprosy of Naaman will cling to you and your descendants forever!” And as Gehazi left his presence, he was leprous—as white as snow.

Context

25Nígbà náà ó sì wọlé wá ó sì dúró níwájú ọ̀gá rẹ̀ Eliṣa. “Níbo ni o ti wà Gehasi?” Eliṣa béèrè. “Ìránṣẹ́ rẹ kò lọ sí ibìkan kan.” Gehasi dá a lóhùn. 26Ṣùgbọ́n Eliṣa wí fún un pé, “Ẹ̀mí mi kò ha wà pẹ̀lú rẹ nígbà tí ọkùnrin náà sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ? Ṣé àsìkò tí ó yẹ láti gba owó nìyìí, tàbí láti gba aṣọ, ọgbà olifi, ọgbà àjàrà, àgùntàn, màlúù tàbí ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin? 27Ẹ̀tẹ̀ Naamani yóò lẹ̀ mọ́ ọ àti sí irú-ọmọ rẹ títí láé.” Nígbà náà Gehasi kúrò níwájú Eliṣa, ó sì di adẹ́tẹ̀, ó sì funfun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.