2 Ọba 4:38
2 Kings 4:38 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Eliṣa padà sí Gilgali ìyàn sì wà ní ilẹ̀ náà. Nígbà tí àwọn ọmọ wòlíì ṣe ìpàdé pẹ̀lú rẹ̀, ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Gbé ìkòkò ńlá ka iná kí o sì se ọbẹ̀ aláta díẹ̀ fún àwọn ọkùnrin yìí.”
2 Kings 4:38 in English
2 Kings 4:38 · Berean Standard Bible
When Elisha returned to Gilgal, there was a famine in the land. As the sons of the prophets were sitting at his feet, he said to his attendant, “Put on the large pot and boil some stew for the sons of the prophets.”
Context
36Eliṣa sì pe Gehasi ó sì wí pé, “Pe ará Ṣunemu.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó dé, ó wí pé, “Gba ọmọ rẹ.” 37Ó sì wọlé, ó sì kúnlẹ̀ síwájú ẹsẹ̀ rẹ̀ ó sì tẹ̀ orí sílẹ̀. Nígbà náà ó sì mú ọmọ rẹ̀ ó sì jáde lọ. 38Eliṣa padà sí Gilgali ìyàn sì wà ní ilẹ̀ náà. Nígbà tí àwọn ọmọ wòlíì ṣe ìpàdé pẹ̀lú rẹ̀, ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Gbé ìkòkò ńlá ka iná kí o sì se ọbẹ̀ aláta díẹ̀ fún àwọn ọkùnrin yìí.” 39Ọ̀kan lára wọn jáde lọ sí orí pápá láti kó ewébẹ̀ jọ àti láti wá àjàrà igbó. Ó sì kó díẹ̀ nínú ẹ̀fọ́ gbọ̀rọ̀ rẹ̀ jọ, ó sì ka a kún aṣọ agbádá rẹ̀. Nígbà tí ó padà dé, ó sì gé wọn sínú ìkòkò ọbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí wọ́n ń jẹ. 40Wọ́n da ọbẹ̀ náà jáde fun àwọn ọkùnrin náà, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ oúnjẹ náà, wọ́n sọkún jáde, “Ìwọ ènìyàn Ọlọ́run ikú ń bẹ nínú ìkòkò yìí!” Wọn kò sì le jẹ ẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.