Native Bible

2 Kings 25:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àti àwọn tí ó kù ní ìlú, ó mú ìwẹ̀fà kan tí ó fi se olórí àwọn ológun, àti ọkùnrin márùn-ún nínú àwọn tó ń gba ọba ní ìmọ̀ràn. Ó sì tún mú akọ̀wé olórí ogun, tí ó ń to àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti ọgọ́ta nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú.

2 Kings 25:19 in English

2 Kings 25:19 · Berean Standard Bible

Of those still in the city, he took a court official who had been appointed over the men of war, as well as five royal advisors. He also took the scribe of the captain of the army, who had enlisted the people of the land, and sixty men who were found in the city.

Context

17Gíga ọ̀wọ́n kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún, àti ọnà-orí rẹ̀ idẹ ni: àti gíga ọnà-orí náà ni ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta; àti iṣẹ́ híhun náà, àti àwọn pomegiranate tí ó wà lórí ọnà-orí náà yíká, gbogbo rẹ̀ ti idẹ ni: gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́n yìí sì ni ọ̀wọ́n kejì pẹ̀lú iṣẹ́ híhun. 18Olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ sì mú gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, Seraiah olórí àwọn àlùfáà, Sefaniah àlùfáà kejì, àti àwọn olùṣọ́ ìloro mẹ́ta. 19Àti àwọn tí ó kù ní ìlú, ó mú ìwẹ̀fà kan tí ó fi se olórí àwọn ológun, àti ọkùnrin márùn-ún nínú àwọn tó ń gba ọba ní ìmọ̀ràn. Ó sì tún mú akọ̀wé olórí ogun, tí ó ń to àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti ọgọ́ta nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú. 20Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn tọ ọba Babeli wá ní Ribla. 21Níbẹ̀ ní Ribla, ní ilẹ̀ Hamati, ọba Babeli sì kọlù wọ́n. Bẹ́ẹ̀ ni a mú Juda kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.