2 Ọba 25:14
2 Kings 25:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sì kó àwọn ìkòkò wọ̀n-ọn-nì, ọkọ́ wọ̀n-ọn-nì, ọ̀pá fìtílà wọ̀n-ọn-nì, síbí wọ̀n-ọn-nì àti gbogbo ohun èlò idẹ wọ̀n-ọn-nì tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ lọ.
2 Kings 25:14 in English
2 Kings 25:14 · Berean Standard Bible
They also took away the pots, shovels, wick trimmers, dishes, and all the articles of bronze used in the temple service.
Context
12Ṣùgbọ́n olórí ẹ̀ṣọ́ fi àwọn tálákà ènìyàn ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti máa bojútó àjàrà àti láti máa ṣe aroko. 13Àwọn ará Babeli fọ́ ọ̀wọ̀n idẹ wọ̀n-ọn-nì àti àwọn ìjókòó wọ̀n-ọn-nì, àti agbada idẹ títóbi wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ilé Olúwa, àwọn ará Babeli fọ́ túútúú, wọ́n sì kó idẹ náà lọ sí Babeli. 14Wọ́n sì kó àwọn ìkòkò wọ̀n-ọn-nì, ọkọ́ wọ̀n-ọn-nì, ọ̀pá fìtílà wọ̀n-ọn-nì, síbí wọ̀n-ọn-nì àti gbogbo ohun èlò idẹ wọ̀n-ọn-nì tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ lọ. 15Olórí ẹ̀ṣọ́ kó ohun ìfọnná wọ̀n-ọn-nì, àti ọpọ́n wọ̀n-ọn-nì, èyí tí wọ́n fi wúrà àti fàdákà ṣe lọ. 16Àwọn ọ̀wọ́n méjì, agbada ńlá kan, àti ìjókòó wọ̀n-ọn-nì tí Solomoni ti ṣe fún ilé Olúwa, idẹ ni gbogbo ohun èló wọ̀nyí, ó ju èyí tí a lé wọ́n lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.