2 Ọba 25:11
2 Kings 25:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nebusaradani olórí ẹ̀ṣọ́ kó gbogbo àwọn tálákà àti gbogbo àwọn tí ó kù ní ìlú, ní ìgbèkùn lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn tí ó ya lọ, tí ó sì ya tọ ọba Babeli lọ, àti ìyókù àwọn ènìyàn náà.
2 Kings 25:11 in English
2 Kings 25:11 · Berean Standard Bible
Then Nebuzaradan captain of the guard carried into exile the people who remained in the city, along with the deserters who had defected to the king of Babylon and the rest of the population.
Context
9ó sì finá sí ilé Olúwa, ilé ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní Jerusalẹmu àti gbogbo ilé ńlá ńlá ni ó dáná sun. 10Gbogbo àwọn ogun Babeli, tí ó wà lọ́dọ̀ olórí ẹ̀ṣọ́, wó ògiri tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀. 11Nebusaradani olórí ẹ̀ṣọ́ kó gbogbo àwọn tálákà àti gbogbo àwọn tí ó kù ní ìlú, ní ìgbèkùn lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn tí ó ya lọ, tí ó sì ya tọ ọba Babeli lọ, àti ìyókù àwọn ènìyàn náà. 12Ṣùgbọ́n olórí ẹ̀ṣọ́ fi àwọn tálákà ènìyàn ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti máa bojútó àjàrà àti láti máa ṣe aroko. 13Àwọn ará Babeli fọ́ ọ̀wọ̀n idẹ wọ̀n-ọn-nì àti àwọn ìjókòó wọ̀n-ọn-nì, àti agbada idẹ títóbi wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ilé Olúwa, àwọn ará Babeli fọ́ túútúú, wọ́n sì kó idẹ náà lọ sí Babeli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.