2 Ọba 24:10
2 Kings 24:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní àkókò náà àwọn ìránṣẹ́ Nebukadnessari ọba Babeli gbé ogun wá Jerusalẹmu, wọ́n sì gbé dó ti ìlú náà,
2 Kings 24:10 in English
2 Kings 24:10 · Berean Standard Bible
At that time the servants of Nebuchadnezzar king of Babylon marched up to Jerusalem, and the city came under siege.
Context
8Jehoiakini jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Nehuṣita ọmọbìnrin Elnatani; ó wá láti Jerusalẹmu. 9Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ ti ṣe. 10Ní àkókò náà àwọn ìránṣẹ́ Nebukadnessari ọba Babeli gbé ogun wá Jerusalẹmu, wọ́n sì gbé dó ti ìlú náà, 11Nebukadnessari ọba Babeli fúnra rẹ̀ wá sókè sí ìlú nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ fi ogun dó tì í. 12Jehoiakini ọba Juda àti ìyá rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìwẹ̀fà àti àwọn ìjòyè gbogbo wọn sì jọ̀wọ́ ara wọn fún un.
Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀ ti ọba Babeli ó mú Jehoiakini ẹlẹ́wọ̀n.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.