2 Ọba 23:31
2 Kings 23:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jehoahasi sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Hamutali ọmọbìnrin Jeremiah; ó wá láti Libina.
2 Kings 23:31 in English
2 Kings 23:31 · Berean Standard Bible
Jehoahaz was twenty-three years old when he became king, and he reigned in Jerusalem three months. His mother’s name was Hamutal daughter of Jeremiah; she was from Libnah.
Context
29Nígbà tí Josiah jẹ́ ọba, Farao Neko ọba Ejibiti gòkè lọ sí odò Eufurate láti lọ ran ọba Asiria lọ́wọ́. Ọba Josiah jáde lọ láti lọ bá a pàdé lójú ogun ṣùgbọ́n Neko dojúkọ ọ́, ó sì pa á ní Megido. 30Ìránṣẹ́ Josiah gbé ara rẹ̀ wá nínú kẹ̀kẹ́ láti Megido sí Jerusalẹmu ó sì sin ín sínú isà òkú rẹ̀. Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú Jehoahasi ọmọ Josiah. Ó fi àmì òróró yàn án, ó sì ṣe é ní ọba ní ipò baba a rẹ̀. 31Jehoahasi sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Hamutali ọmọbìnrin Jeremiah; ó wá láti Libina. 32Ó ṣe búburú lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ ti ṣe. 33Farao Neko sì fi sí inú ìdè ní Ribla ní ilẹ̀ Hamati, kí ó má ba à lè jẹ ọba ní Jerusalẹmu. Ó sì tan Juda jẹ fun iye ìwọ̀n ẹgbẹ̀rin tálẹ́ǹtì wúrà kan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.