2 Ọba 23:11
2 Kings 23:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì kúrò láti ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé sí ilé Olúwa, àwọn ẹṣin tí àwọn ọba Juda ti yà sọ́tọ̀ sí oòrùn náà. Wọ́n wà nínú ilé ẹjọ́ lẹ́bàá yàrá oníṣẹ́ tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Natani-Meleki. Josiah sì sun àwọn kẹ̀kẹ́ tí a yà sọ́tọ̀ fún oòrùn.
2 Kings 23:11 in English
2 Kings 23:11 · Berean Standard Bible
And he removed from the entrance to the house of the LORD the horses that the kings of Judah had dedicated to the sun. They were in the court * near the chamber of an official named Nathan-melech. And Josiah burned up the chariots of the sun.
Context
9Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, àwọn àlùfáà ibi gíga kò jọ́sìn ní ibi pẹpẹ Olúwa ní Jerusalẹmu, wọ́n jẹ nínú àkàrà aláìwú pẹ̀lú àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn. 10Ó sì ba ohun mímọ́ Tofeti jẹ́, tí ó wà ní àfonífojì Beni-Hinnomu, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkan tí ó lè lò ó fún ẹbọ rírú fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin nínú iná sí Moleki. 11Ó sì kúrò láti ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé sí ilé Olúwa, àwọn ẹṣin tí àwọn ọba Juda ti yà sọ́tọ̀ sí oòrùn náà. Wọ́n wà nínú ilé ẹjọ́ lẹ́bàá yàrá oníṣẹ́ tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Natani-Meleki. Josiah sì sun àwọn kẹ̀kẹ́ tí a yà sọ́tọ̀ fún oòrùn. 12Ó wó o palẹ̀ pẹpẹ tí àwọn ọba Juda ti wọ́n gbé dúró ní orí òrùlé lẹ́bàá yàrá òkè ti Ahasi pẹ̀lú àwọn pẹpẹ tí Manase ti kọ́ nínú ilé ẹjọ́ méjèèjì sí ilé Olúwa. Ó ṣí wọn kúrò níbẹ̀, ó fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́. Ó sì da ekuru wọn sínú àfonífojì Kidironi. 13Ọba pẹ̀lú ba ohun mímọ́ àwọn ibi gíga jẹ́ tí ó wà ní ìhà ìlà-oòrùn Jerusalẹmu ní ìhà gúúsù ti òkè ìbàjẹ́—èyí tí Solomoni ọba Israẹli ti kọ́ fún Aṣtoreti ọlọ́run ìríra àwọn ará Sidoni, fún Kemoṣi ọlọ́run ìríra àwọn ará Moabu àti fún Moleki, ọlọ́run ìríra àwọn ènìyàn Ammoni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.