2 Ọba 22:7
2 Kings 22:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n wọn kò ní láti ṣe ìṣirò fún owó náà tí a fi fún wọn, nítorí wọ́n ṣe òtítọ́.”
2 Kings 22:7 in English
2 Kings 22:7 · Berean Standard Bible
But they need not account for the money put into their hands, since they work with integrity.”
Context
5Ẹ sì jẹ́ kí wọn ó fi lé àwọn ọkùnrin tí a ti yàn láti bojútó iṣẹ́ náà lórí ilé Olúwa. Kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn ọkùnrin san án fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń tún ilé Olúwa ṣe. 6Àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn akọ́lé. Bákan náà ni wọ́n ra igi àti òkúta ọlọ́ṣọ̀ọ́ láti fi tún tẹmpili ṣe. 7Ṣùgbọ́n wọn kò ní láti ṣe ìṣirò fún owó náà tí a fi fún wọn, nítorí wọ́n ṣe òtítọ́.” 8Hilkiah olórí àlùfáà sọ fún Ṣafani akọ̀wé pé, “Èmi rí ìwé òfin nílé Olúwa.” Ó fi fún Ṣafani, ẹni tí ó kà á. 9Nígbà náà, Ṣafani akọ̀wé lọ sí ọ̀dọ̀ ọba. Ó sì sọ fún un pé, “Àwọn ìjòyè rẹ ti san owó náà tí ó wà nínú ilé Olúwa. Èmi sì ti fi lé ọwọ́ àwọn tí ó ń ṣe iṣẹ́ náà àti àwọn alábojútó nílé Olúwa.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.