Native Bible

2 Kings 22:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí tí ọkàn rẹ rọ̀, tí ìwọ sì ti rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Olúwa, nígbà tí ìwọ gbọ́ èyí tí mo sọ sí ibí yìí àti sí àwọn ènìyàn rẹ pé wọn yóò di ahoro àti ẹni ègún tí ìwọ sì fa aṣọ ọ̀ rẹ ya pẹ̀lú níwájú mi. Èmi ti gbọ́ tìrẹ, ni Olúwa wí.

2 Kings 22:19 in English

2 Kings 22:19 · Berean Standard Bible

because your heart was tender and you humbled yourself before the LORD when you heard what I spoke against this place and against its people, that they would become a desolation and a curse, and because you have torn your clothes and wept before Me, I have heard you,’ declares the LORD.

Context

17Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì tún sun tùràrí fún ọlọ́run mìíràn. Wọ́n sì mú mi bínú nípa gbogbo àwọn òrìṣà tí wọ́n ti fi ọwọ́ wọn dá. Ìbínú mi yóò ru sí ibí yìí, kì yóò sì rọlẹ̀.’ 18Sọ fún ọba Juda tí ó rán yín láti béèrè lọ́wọ́ Olúwa, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí nípa ọ̀rọ̀ wọ̀n-ọn-nì tí ìwọ ti gbọ́. 19Nítorí tí ọkàn rẹ rọ̀, tí ìwọ sì ti rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Olúwa, nígbà tí ìwọ gbọ́ èyí tí mo sọ sí ibí yìí àti sí àwọn ènìyàn rẹ pé wọn yóò di ahoro àti ẹni ègún tí ìwọ sì fa aṣọ ọ̀ rẹ ya pẹ̀lú níwájú mi. Èmi ti gbọ́ tìrẹ, ni Olúwa wí. 20Nítorí náà èmi yóò kó ọ jọ sí ọ̀dọ̀ àwọn baba à rẹ, a ó sì sin ọ́ ní àlàáfíà. Ojú rẹ kì yóò rí gbogbo àwọn ibi tí èmi yóò mú wá bá ibí yìí.’ ” Bẹ́ẹ̀ wọ́n mú èsì rẹ̀ padà tọ ọba wá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.