2 Ọba 21:7
2 Kings 21:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì gbé ère fínfín òrìṣà Aṣerah tí ó ti ṣe, ó sì gbé e sínú ilé Olúwa, èyí tí Olúwa ti sọ fún Dafidi àti sí ọmọ rẹ̀ Solomoni, “Nínú ilé Olúwa yìí àti ní Jerusalẹmu, tí èmi ti yàn jáde lára gbogbo ẹ̀yà Israẹli, èmi yóò kọ orúkọ mi títí láéláé.
2 Kings 21:7 in English
2 Kings 21:7 · Berean Standard Bible
Manasseh even took the carved Asherah pole he had made and set it up in the temple, of which the LORD had said to David and his son Solomon, “In this temple and in Jerusalem, which I have chosen out of all the tribes of Israel, I will establish My Name forever.
Context
5Ní àgbàlá méjèèjì ilé Olúwa, ó sì kọ́ pẹpẹ fún gbogbo àwọn ìrúbọ nínú ilé, ṣe iṣẹ́ àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì béèrè lọ́wọ́ àwọn òkú àti àwọn oṣó. Ó sì ṣe ọ̀pọ̀ búburú ní ojú Olúwa, ó sì mú un bínú. 6Ó fi àwọn ọmọ ara rẹ̀ rú ẹbọ nínú iná, ó ń ṣe àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì ń lo àlúpàyídà, ó sì ń bá àwọn òku àti oṣó lò. Ó ṣe ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú Olúwa láti mú un bínú. 7Ó sì gbé ère fínfín òrìṣà Aṣerah tí ó ti ṣe, ó sì gbé e sínú ilé Olúwa, èyí tí Olúwa ti sọ fún Dafidi àti sí ọmọ rẹ̀ Solomoni, “Nínú ilé Olúwa yìí àti ní Jerusalẹmu, tí èmi ti yàn jáde lára gbogbo ẹ̀yà Israẹli, èmi yóò kọ orúkọ mi títí láéláé. 8Èmi kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli yẹ̀ kúrò láti ilẹ̀ tí èmi fi fún àwọn baba ńlá wọn tí ó bá jẹ́ wí pé wọn yóò ṣe àkíyèsí láti ṣe gbogbo ohun tí èmi ti paláṣẹ fún wọn kí wọn sì pa gbogbo òfin tí ìránṣẹ́ mi Mose fi fún wọn mọ́.” 9Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tẹ́tí. Manase tàn wọ́n síwájú, bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n lè ṣe búburú ju gbogbo orílẹ̀-èdè tí Olúwa tí parun níwájú àwọn ọmọ Israẹli lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.