Native Bible

2 Kings 21:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì tún ibi gíga tí baba rẹ̀ Hesekiah tí ó parun kọ́. Ó sì tún gbé pẹpẹ Baali dìde, ó sì ṣe ère òrìṣà Aṣerah, gẹ́gẹ́ bí Ahabu ọba Israẹli ti ṣe. Ó sì tẹríba sí gbogbo ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n.

2 Kings 21:3 in English

2 Kings 21:3 · Berean Standard Bible

For he rebuilt the high places that his father Hezekiah had destroyed, and he raised up altars for Baal. He made an Asherah pole, as King Ahab of Israel had done, and he worshiped and served all the host of heaven.

Context

1Manase jẹ́ ẹni ọdún méjìlá nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún márùndínlọ́gọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Hẹfisiba. 2Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, ó sì tẹ̀lé iṣẹ́ ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli. 3Ó sì tún ibi gíga tí baba rẹ̀ Hesekiah tí ó parun kọ́. Ó sì tún gbé pẹpẹ Baali dìde, ó sì ṣe ère òrìṣà Aṣerah, gẹ́gẹ́ bí Ahabu ọba Israẹli ti ṣe. Ó sì tẹríba sí gbogbo ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n. 4Ó sì kọ́ pẹpẹ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa, èyí tí Olúwa ti sọ pé, “Ní Jerusalẹmu ni èmi yóò kọ orúkọ mi sí.” 5Ní àgbàlá méjèèjì ilé Olúwa, ó sì kọ́ pẹpẹ fún gbogbo àwọn ìrúbọ nínú ilé, ṣe iṣẹ́ àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì béèrè lọ́wọ́ àwọn òkú àti àwọn oṣó. Ó sì ṣe ọ̀pọ̀ búburú ní ojú Olúwa, ó sì mú un bínú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.