2 Ọba 19:6
2 Kings 19:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Isaiah wí fún wọn pé, “Sọ fún ọ̀gá rẹ, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa sọ pé: Ẹ má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ̀yin ti gbọ́—àwọn ọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ pẹ̀lú èyí ti ọba Asiria ti sọ̀rọ̀-òdì sí mi.
2 Kings 19:6 in English
2 Kings 19:6 · Berean Standard Bible
who replied, “Tell your master that this is what the LORD says: ‘Do not be afraid of the words you have heard, with which the servants of the king of Assyria have blasphemed Me.
Context
4Ó lè jẹ́ wí pé Olúwa Ọlọ́run yóò gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ olùdarí pápá, ẹni tí ọ̀gá rẹ̀, ọba Asiria, ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè ṣẹ̀sín, yóò sì bá a wí fún ọ̀rọ̀ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún ìyókù àwọn tí ó wà láààyè.” 5Nígbà tí ìránṣẹ́ ọba Hesekiah lọ sí ọ̀dọ̀ Isaiah, 6Isaiah wí fún wọn pé, “Sọ fún ọ̀gá rẹ, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa sọ pé: Ẹ má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ̀yin ti gbọ́—àwọn ọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ pẹ̀lú èyí ti ọba Asiria ti sọ̀rọ̀-òdì sí mi. 7Gbọ́! Èmi yóò rán ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ nígbà tí ó bá sì gbọ́ ariwo, yóò sì padà sí ìlú rẹ̀, níbẹ̀ ni èmi yóò sì gbé gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà.’ ” 8Nígbà tí olùdarí pápá gbọ́ wí pé ọba Asiria ti kúrò ní Lakiṣi ó sì padà ó sì rí ọba níbi ti ó gbé ń bá Libina jà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.