2 Ọba 19:37
2 Kings 19:37 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ó sùn nínú ilé òrìṣà Nisroki, ọmọkùnrin rẹ̀ Adrameleki àti Ṣareseri gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n sì sálọ sí ilẹ̀ Ararati Esarhadoni ọmọkùnrin rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
2 Kings 19:37 in English
2 Kings 19:37 · Berean Standard Bible
One day, while he was worshiping in the temple of his god Nisroch, his sons Adrammelech and Sharezer * put him to the sword and escaped to the land of Ararat. And his son Esar-haddon reigned in his place.
Context
35Ní alẹ́ ọjọ́ náà, angẹli Olúwa jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (185,000) ènìyàn ní ibùdó àwọn ará Asiria. Nígbà tí wọ́n sì dìde dúró ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì níbẹ̀ ni gbogbo òkú wà! 36Bẹ́ẹ̀ ni Sennakeribu ọba Asiria wọ àgọ́ ó sì padà, ó sì padà sí Ninefe ó sì dúró níbẹ̀. 37Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ó sùn nínú ilé òrìṣà Nisroki, ọmọkùnrin rẹ̀ Adrameleki àti Ṣareseri gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n sì sálọ sí ilẹ̀ Ararati Esarhadoni ọmọkùnrin rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.