2 Ọba 19:16
2 Kings 19:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dẹtí sílẹ̀, Olúwa kí o sì gbọ́; la ojú rẹ, Olúwa, kí o sì rí i, gbọ́ ọ̀rọ̀ Sennakeribu tí ó rán láti fi bú Ọlọ́run alààyè.
2 Kings 19:16 in English
2 Kings 19:16 · Berean Standard Bible
Incline Your ear, O LORD, and hear; open Your eyes, O LORD, and see. Listen to the words that Sennacherib has sent to defy the living God.
Context
14Hesekiah gba lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ ó sì kà á. Nígbà náà ó sì lọ sí òkè ilé tí a kọ́ fún Olúwa ó sì tẹ́ ẹ síwájú Olúwa. 15Hesekiah gbàdúrà sí Olúwa: “Olúwa Ọlọ́run Israẹli, tí ń gbé ní àárín àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lórí gbogbo ìjọba tí ó wà láyé, ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé. 16Dẹtí sílẹ̀, Olúwa kí o sì gbọ́; la ojú rẹ, Olúwa, kí o sì rí i, gbọ́ ọ̀rọ̀ Sennakeribu tí ó rán láti fi bú Ọlọ́run alààyè. 17“Òtítọ́ ni, Olúwa, wí pé ọba Asiria ti pa orílẹ̀-èdè wọ̀nyí run àti ilẹ̀ wọn. 18Wọ́n ti ju òrìṣà wọn sínú iná wọn sì ti bà wọ́n jẹ́, nítorí pé wọn kì í ṣe ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, wọ́n jẹ́ igi àti òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ọwọ́ ènìyàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.