Native Bible

2 Kings 19:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lóòótọ́ ìwọ ti gbọ́ gbogbo ohun tí ọba Asiria tí ó ṣe sí gbogbo àwọn ìlú, ó pa wọ́n run pátápátá. Ìwọ yóò sì gbàlà?

2 Kings 19:11 in English

2 Kings 19:11 · Berean Standard Bible

Surely you have heard what the kings of Assyria have done to all the other countries, devoting them to destruction.* Will you then be spared?

Context

9Nísinsin yìí, Sennakeribu sì gbọ́ ìròyìn wí pé Tirakah, ọba Etiopia ti Ejibiti wá ó sì ń yan jáde lọ láti lọ bá a jagun. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tún rán oníṣẹ́ sí Hesekiah pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí pé, 10“Sọ fún Hesekiah ọba Juda pé, má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé kí ó tàn ó jẹ nígbà tí ó wí pé, ‘Jerusalẹmu a kò ní fi lé ọwọ́ ọba Asiria.’ 11Lóòótọ́ ìwọ ti gbọ́ gbogbo ohun tí ọba Asiria tí ó ṣe sí gbogbo àwọn ìlú, ó pa wọ́n run pátápátá. Ìwọ yóò sì gbàlà? 12Ṣé àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè tí a ti parun láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá mi gbà wọ́n là: òrìṣà Gosani, Harani Reṣefu àti gbogbo ènìyàn Edeni tí wọ́n wà ní Teli-Assari? 13Níbo ni ọba Hamati wa, ọba Arpadi, ọba ìlú Sefarfaimi, ti Hena, tàbí ti Iffa gbé wà?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.