Native Bible

2 Kings 18:35 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ta ni nínú gbogbo àwọn òrìṣà ilẹ̀ yìí tí ó ti gbìyànjú láti gba ilẹ̀ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi? Báwo ni Olúwa yóò ṣe gba Jerusalẹmu kúrò lọ́wọ́ mi?”

2 Kings 18:35 in English

2 Kings 18:35 · Berean Standard Bible

Who among all the gods of these lands has delivered his land from my hand? How then can the LORD deliver Jerusalem from my hand?”

Context

33Ṣé òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè kankan ti gba ilé rẹ lọ́wọ́ àwọn ọba Asiria? 34Níbo ni àwọn òrìṣà Hamati àti Arpadi gbé wà? Níbo ni àwọn òrìṣà Sefarfaimi, Hena àti Iffa gbé wà? Wọ́n ha gba Samaria kúrò lọ́wọ́ mi bí? 35Ta ni nínú gbogbo àwọn òrìṣà ilẹ̀ yìí tí ó ti gbìyànjú láti gba ilẹ̀ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi? Báwo ni Olúwa yóò ṣe gba Jerusalẹmu kúrò lọ́wọ́ mi?” 36Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ènìyàn náà dákẹ́ síbẹ̀ wọn kò sì sọ ohunkóhun, láti fi fèsì, nítorí ọba ti paláṣẹ, “Ẹ má ṣe dá a lóhùn.” 37Nígbà náà Eliakimu ọmọ Hilkiah olùtọ́jú ààfin, Ṣebna akọ̀wé àti Joah ọmọ Asafu akọ̀wé ránṣẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekiah, pẹ̀lú aṣọ wọn yíya, ó sì wí fún un ohun tí olùdarí pápá ti sọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.