Native Bible

2 Kings 17:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó ti kúrò ní Samaria wá gbé ní Beteli ó sì kọ́ wọn bí a ti ń sin Olúwa.

2 Kings 17:28 in English

2 Kings 17:28 · Berean Standard Bible

Thus one of the priests they had carried away came and lived in Bethel, and he began to teach them how they should worship the LORD.

Context

26Wọ́n sì sọ fún ọba Asiria pé, “Àwọn ènìyàn tí ìwọ lé kúrò tí o sì fi sínú ìlú Samaria kò mọ ohun tí ọlọ́run ìlú náà béèrè. Ó sì ti rán kìnnìún sí àárín wọn, tí ó sì ń pa wọ́n run, nítorí ènìyàn wọn kò mọ ohun tí ó béèrè.” 27Nígbà náà ọba Asiria pàṣẹ yìí wí pé, “Mú ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó mú láti Samaria lọ padà gbé níbẹ̀ kí ó sì kọ́ àwọn ènìyàn ní, ohun tí ọlọ́run ilẹ̀ náà béèrè.” 28Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó ti kúrò ní Samaria wá gbé ní Beteli ó sì kọ́ wọn bí a ti ń sin Olúwa. 29Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, olúkúlùkù orílẹ̀-èdè ṣe òrìṣà tirẹ̀ ní gbogbo ìlú níbi tí wọ́n gbé wà, wọ́n sì gbé wọn nínú ilé òrìṣà àti àwọn ènìyàn Samaria ó sì ṣe wọ́n sí ibi gíga wọ̀n-ọn-nì. 30Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin láti Babeli ṣe àgọ́ àwọn wúńdíá, àwọn ènìyàn Kuti ṣe òrìṣà Nergali, àti àwọn ènìyàn Hamati ṣe ti Aṣima;

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.