2 Ọba 14:6
2 Kings 14:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Síbẹ̀ kò pa ọmọ àwọn apànìyàn náà. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ sínú ìwé òfin Mose níbi tí Olúwa ti paláṣẹ pé, “A kì yóò pa baba nítorí àwọn ọmọ, tàbí àwọn ọmọ nítorí àwọn baba; olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”
2 Kings 14:6 in English
2 Kings 14:6 · Berean Standard Bible
Yet he did not put the sons of the murderers to death, but acted according to what is written in the Book of the Law of Moses, where the LORD commanded: “Fathers must not be put to death for their children, and children must not be put to death for their fathers; each is to die for his own sin.”*
Context
4Àwọn ibi gíga bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí i kúrò, àwọn ènìyàn sì tẹ̀síwájú láti rú ẹbọ àti sun tùràrí níbẹ̀. 5Lẹ́yìn tí ó ti fi ọwọ́ gbá ìjọba rẹ̀ mú gbọingbọin, ó pa àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n ti pa baba a rẹ̀ ọba. 6Síbẹ̀ kò pa ọmọ àwọn apànìyàn náà. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ sínú ìwé òfin Mose níbi tí Olúwa ti paláṣẹ pé, “A kì yóò pa baba nítorí àwọn ọmọ, tàbí àwọn ọmọ nítorí àwọn baba; olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” 7Òun ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ará Edomu ní àfonífojì iyọ̀, ó sì fi agbára mú Sela nínú ogun, tí ó ń pè é ní Jokteeli, orúkọ tí ó ní títí di òní. 8Nígbà náà, Amasiah rán àwọn ìránṣẹ́ sí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọmọ Jehu ọba Israẹli pẹ̀lú ìpèníjà: “Wá, jẹ́ kí á wo ara wa ní ojú.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.