2 Ọba 13:22
2 Kings 13:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Hasaeli ọba Siria ni Israẹli lára ní gbogbo àkókò tí Jehoahasi fi jẹ ọba.
2 Kings 13:22 in English
2 Kings 13:22 · Berean Standard Bible
And Hazael king of Aram oppressed Israel throughout the reign of Jehoahaz.
Context
20Eliṣa kú a sì sin ín.
Ẹgbẹ́ àwọn ará Moabu máa ń wọ orílẹ̀-èdè ní gbogbo àmọ́dún. 21Bí àwọn ọmọ Israẹli kan ti ń sin òkú ọkùnrin kan, lójijì wọ́n rí ẹgbẹ́ àwọn oníjadì, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ju òkú ọkùnrin náà sínú ibojì Eliṣa. Nígbà tí ara ọkùnrin náà kan egungun Eliṣa, ó padà wá sí ayé, ó sì dúró ní ẹsẹ̀ rẹ̀. 22Hasaeli ọba Siria ni Israẹli lára ní gbogbo àkókò tí Jehoahasi fi jẹ ọba. 23Ṣùgbọ́n Olúwa ṣàánú fún wọn ó sì ní ìyọ́nú, ó sì fiyèsí wọn nítorí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu. Títí di ọjọ́ òní, kì í ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ láti pa wọ́n run tàbí lé wọn lọ níwájú rẹ̀. 24Hasaeli ọba Siria kú, Beni-Hadadi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.