2 Ọba 12:20
2 Kings 12:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ sí i wọ́n sì lù ú pa ní Beti-Milo ní ọ̀nà sí Silla.
2 Kings 12:20 in English
2 Kings 12:20 · Berean Standard Bible
And the servants of Joash rose up and formed a conspiracy and killed him at Beth-millo, on the road down to Silla.
Context
18Ṣùgbọ́n Jehoaṣi ọba Juda mú gbogbo ohun mímọ́ tí a gbé ka iwájú tí a yà sọ́tọ̀ nípasẹ̀ baba rẹ̀ Jehoṣafati, Jehoramu àti Ahasiah, àwọn ọba Juda, àti àwọn ẹ̀bùn tí òun tìkára rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ àti gbogbo wúrà, tí ó rí nínú ibi ìfowópamọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa àti ní ti ààfin ọba, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Hasaeli; ọba Siria, tí ó sì fà padà kúrò ní Jerusalẹmu. 19Pẹ̀lú ìyókù ìṣe Joaṣi, àti ohun gbogbo tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda? 20Àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ sí i wọ́n sì lù ú pa ní Beti-Milo ní ọ̀nà sí Silla. 21Àwọn oníṣẹ́ tí ó pa á jẹ́ Josabadi ọmọ Ṣimeati àti Jehosabadi ọmọ Ṣomeri. Ó kú, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú baba rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dafidi. Amasiah ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.