Native Bible

2 Kings 12:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A sì san án fún àwọn ọkùnrin tí ó ń ṣiṣẹ́, tí wọ́n ń tọ́jú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

2 Kings 12:14 in English

2 Kings 12:14 · Berean Standard Bible

Instead, it was paid to those doing the work, and with it they repaired the house of the LORD.

Context

12Àwọn ilé ńlá àti àwọn agékúta. Wọ́n ra igi gẹdú àti òkúta tí wọ́n tọ́jú fún tuntun ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe. Wọ́n tún ohun gbogbo tí wọ́n ná fún títún tẹmpili ṣe. 13Owó tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa kò jẹ́ níná fún ṣíṣe òpó fàdákà, ohun èlò ta fi ń fa ẹnu fìtílà, àwokòtò, ìpè, ohun èlò wúrà tàbí ohun èlò fàdákà kan fún ilé tí a kọ́ fún Olúwa. 14A sì san án fún àwọn ọkùnrin tí ó ń ṣiṣẹ́, tí wọ́n ń tọ́jú ilé tí a kọ́ fún Olúwa. 15Wọn kò sì bá àwọn ọkùnrin náà ṣírò, ní ọwọ́ ẹni tí wọ́n fún ní owó láti san fún àwọn òṣìṣẹ́. Torí wọ́n ṣe é pẹ̀lú òdodo tí ó pé. 16Owó láti ibi ọrẹ ẹ̀bi àti ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ ní a kò mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa, ó jẹ́ ti àwọn àlùfáà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.