Native Bible

2 Kings 10:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jehu wí pé, “Wá pẹ̀lú mi, kí o sì rí ìtara mi fún Olúwa.” Nígbà náà ó jẹ́ kí ó gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀.

2 Kings 10:16 in English

2 Kings 10:16 · Berean Standard Bible

saying, “Come with me and see my zeal for the LORD!” So he had him ride * in his chariot.

Context

14“Mú wọn láààyè!” ó pàṣẹ. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n mú wọn láààyè, wọ́n sì pa wọ́n ní ẹ̀bá kọ̀nga Beti-Ekedi, ọkùnrin méjìlélógójì. Kò sì fi ẹnìkan sílẹ̀ láìkù. 15Nígbà tí a sì jáde níbẹ̀, ó rí Jehonadabu ọmọ Rekabu ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀, ó sì súre fún un, ó sì wí fún pé, “Ọkàn rẹ ha ṣe déédé bí ọkàn mi ti rí sí ọkàn rẹ?” Jehonadabu dáhùn wí pé, “Èmi wà.” Jehu wí pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, fún mi ní ọwọ́ ọ̀ rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe pẹ̀lú, Jehu sì fà á lọ́wọ́ sókè sọ́dọ̀ rẹ̀ nínú kẹ̀kẹ́. 16Jehu wí pé, “Wá pẹ̀lú mi, kí o sì rí ìtara mi fún Olúwa.” Nígbà náà ó jẹ́ kí ó gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀. 17Nígbà tí Jehu wá sí Samaria, ó pa gbogbo àwọn tí a fi kalẹ̀ ní ìdílé Ahabu; ó pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ sí Elijah. 18Nígbà náà, Jehu kó gbogbo àwọn ènìyàn jọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ahabu sin Baali díẹ̀; ṣùgbọ́n Jehu yóò sìn ín púpọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.