Native Bible

2 Kings 1:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sọ fún ọba pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí, ‘Ṣé nítorí wí pé kò sí Ọlọ́run ní Israẹli fún ọ láti pè ni ìwọ fi rán ìránṣẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ Baali-Sebubu, òrìṣà Ekroni láti lọ ṣe ìwádìí?’ Nítorí pé o ṣe èyí, ìwọ kò ní dìde lórí ibùsùn tí o dùbúlẹ̀ lé láìsí àní àní ìwọ yóò kú!”

2 Kings 1:16 in English

2 Kings 1:16 · Berean Standard Bible

And Elijah said to King Ahaziah, “This is what the LORD says: Is there really no God in Israel for you to inquire of His word? Is that why you have sent messengers to inquire of Baal-zebub, the god of Ekron? Therefore you will not get up from the bed on which you are lying. You will surely die.”

Context

14Wò ó, iná ti sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run láti jó àwọn balógun méjì àràádọ́ta àkọ́kọ́ pẹ̀lú àràádọ́ta wọn. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ní ojúrere fún ẹ̀mí mi!” 15Angẹli Olúwa sọ fún Elijah pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀; má ṣe bẹ̀rù rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni Elijah dìde ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba. 16Ó sọ fún ọba pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí, ‘Ṣé nítorí wí pé kò sí Ọlọ́run ní Israẹli fún ọ láti pè ni ìwọ fi rán ìránṣẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ Baali-Sebubu, òrìṣà Ekroni láti lọ ṣe ìwádìí?’ Nítorí pé o ṣe èyí, ìwọ kò ní dìde lórí ibùsùn tí o dùbúlẹ̀ lé láìsí àní àní ìwọ yóò kú!” 17Bẹ́ẹ̀ ó sì kú, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí Elijah ti sọ. Nítorí Ahasiah kò ní ọmọ, Jehoramu jẹ ọba ní ọdún kejì tí Jehoramu ọmọ Jehoṣafati ọba Juda. 18Àti ní ti gbogbo àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba Ahasiah, àti ohun tí ó ṣe, ṣe a kò ha kọ wọ́n sí inú ìwé ọdọọdún ti àwọn ọba Israẹli?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.