Native Bible

2 Kings 1:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Tí èmi bá jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run,” Elijah sì dáhùn, “Ǹjẹ́ kí iná kí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run kí ó sì jó ọ run àti àwọn àádọ́ta ènìyàn rẹ!” Nígbà náà iná Ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run ó sì jó o run pẹ̀lú àwọn àádọ́ta ènìyàn rẹ̀.

2 Kings 1:12 in English

2 Kings 1:12 · Berean Standard Bible

Again Elijah replied, “If I am a man of God, may fire come down from heaven and consume you and your fifty men.” And the fire of God came down from heaven and consumed the captain and his fifty men.

Context

10Elijah sì dá balógun lóhùn pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ènìyàn Ọlọ́run ni mí, kí iná kí ó sọ̀kalẹ̀ láti òkè ọ̀run wá kí ó sì jó ìwọ àti àwọn àádọ́ta ọkùnrin rẹ!” Nígbà náà iná náà sì sọ̀kalẹ̀ wá láti òkè ọ̀run ó sì jó balógun àti àwọn ènìyàn rẹ̀. 11Ọba sì tún rán balógun àádọ́ta pẹ̀lú àwọn ènìyàn àádọ́ta rẹ̀ sí Elijah. Balógun náà sì wí fún un pé, “Ènìyàn Ọlọ́run, èyí ni ohun tí ọba sọ, ‘Sọ̀kalẹ̀ kánkán!’ ” 12“Tí èmi bá jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run,” Elijah sì dáhùn, “Ǹjẹ́ kí iná kí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run kí ó sì jó ọ run àti àwọn àádọ́ta ènìyàn rẹ!” Nígbà náà iná Ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run ó sì jó o run pẹ̀lú àwọn àádọ́ta ènìyàn rẹ̀. 13Bẹ́ẹ̀ ni ọba tún rán balógun kẹta pẹ̀lú àwọn àádọ́ta ọkùnrin. Balógun ẹ̀ẹ̀kẹ́ta lọ sí òkè, ó sì kúnlẹ̀ lórí orókún rẹ̀ níwájú Elijah. “Ènìyàn Ọlọ́run,” Ó sì bẹ̀bẹ̀ pé, “Ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, jọ̀wọ́ jẹ́ kí ẹ̀mí mi àti ẹ̀mí àwọn àádọ́ta ìránṣẹ́ rẹ wọ̀nyí ṣọ̀wọ́n ní ojú rẹ! 14Wò ó, iná ti sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run láti jó àwọn balógun méjì àràádọ́ta àkọ́kọ́ pẹ̀lú àràádọ́ta wọn. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ní ojúrere fún ẹ̀mí mi!”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.