Native Bible

2 Corinthians 8:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ parí ṣíṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú; kí ó ba à lè ṣe pé, bí ìpinnu fún ṣíṣe ti wà, bẹ́ẹ̀ ni kí ìparí sì wà láti inú agbára yín.

2 Corinthians 8:11 in English

2 Corinthians 8:11 · Berean Standard Bible

Now finish the work, so that you may complete it just as eagerly as you began, according to your means.

Context

9Nítorí ẹ̀yin mọ oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa Jesu Kristi, pé bí òun ti jẹ́ ọlọ́rọ̀ rí ṣùgbọ́n nítorí yín ó di tálákà kí a lè sọ yín di ọlọ́rọ̀ nípa àìní rẹ̀. 10Àti nínú èyí ni mo fi ìmọ̀ràn mi fún yín, nítorí èyí ṣe àǹfààní fún yín, ẹ̀yin tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ níwọ̀n ọdún tí ó kọjá, kì í ṣe láti ṣe nǹkan, ṣùgbọ́n láti fẹ́ pẹ̀lú. 11Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ parí ṣíṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú; kí ó ba à lè ṣe pé, bí ìpinnu fún ṣíṣe ti wà, bẹ́ẹ̀ ni kí ìparí sì wà láti inú agbára yín. 12Nítorí bí ìpinnu bá wà ṣáájú, ó jásí ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ohun tí ènìyàn bá ní, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò ní. 13Nítorí èmi kò fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn wà ní ìrọ̀rùn, kí ó sì jẹ́ ìpọ́njú fún yín, ṣùgbọ́n pé nípa mímú dọ́gba.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.