2 Kọrinti 7:12
2 Corinthians 7:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, bí mo tilẹ̀ tí kọ̀wé sí yín, èmi kò kọ ọ́ nítorí ẹni tí ó ṣe ohun búburú náà tàbí nítorí ẹni ti a fi ohun búburú náà ṣe, ṣùgbọ́n kí àníyàn yín nítorí wá lè farahàn níwájú Ọlọ́run.
2 Corinthians 7:12 in English
2 Corinthians 7:12 · Berean Standard Bible
So even though I wrote to you, it was not on account of the one who did wrong or the one who was harmed, but rather that your earnestness on our behalf would be made clear to you in the sight of God.
Context
10Nítorí pé ìbànújẹ́ ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run máa ṣiṣẹ́ ìrònúpìwàdà sí ìgbàlà tí kì í mú àbámọ̀ wá, ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ti ayé a máa ṣiṣẹ́ ikú. 11Kíyèsi i, nítorí ohun kan náà yìí tí a mú yin banújẹ́ fún bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, irú ìmúraṣíṣẹ́ tí ó mú jáde nínú yín, wíwẹ ara yín mọ́ ń kọ́, ìbànújẹ́ ń kọ́, ìpayà ń kọ́, ìfojúṣọ́nà ń kọ́, ìtara ń kọ́, ìjẹ́ni-níyà ń kọ́. Nínú ohun àmì kọ̀ọ̀kan yìí ni ẹ̀yin ti fi ara yín hàn bí aláìlẹ́bi nínú ọ̀ràn náà. 12Nítorí náà, bí mo tilẹ̀ tí kọ̀wé sí yín, èmi kò kọ ọ́ nítorí ẹni tí ó ṣe ohun búburú náà tàbí nítorí ẹni ti a fi ohun búburú náà ṣe, ṣùgbọ́n kí àníyàn yín nítorí wá lè farahàn níwájú Ọlọ́run. 13Nítorí náà, a tí fi ìtùnú yín tù wá nínú.
Àti nínú ìtùnú wa, a yọ̀ gidigidi nítorí pé Titu ní ayọ̀, nítorí láti ọ̀dọ̀ gbogbo yín ni a ti tu ẹ̀mí rẹ̀ lára. 14Bí mo tilẹ̀ ti lérí ohunkóhun fún ún nítorí yín, a kò dójútì mí; ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àwa ti sọ ohun gbogbo fún yín ní òtítọ́, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ìlérí wá níwájú Titu sì jásí òtítọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.