2 Kọrinti 6:4
2 Corinthians 6:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ni ọnà gbogbo, àwa ń fi ara wa hàn bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùúrù, nínú ìpọ́njú, nínú àìní, nínú wàhálà,
2 Corinthians 6:4 in English
2 Corinthians 6:4 · Berean Standard Bible
Rather, as servants of God we commend ourselves in every way: in great endurance; in troubles, hardships, and calamities;
Context
2Nítorí o wí pé,
“Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mi, èmi tí gbọ́ ohùn rẹ,
àti ọjọ́ ìgbàlà, èmi sì ti ràn ọ́ lọ́wọ́.”
Èmi wí fún ọ, nísinsin yìí ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, nísinsin yìí ni ọjọ́ ìgbàlà. 3Àwa kò sì gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ kankan si ọ̀nà ẹnikẹ́ni, ki iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa má ṣe di ìsọ̀rọ̀-òdì sí. 4Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ni ọnà gbogbo, àwa ń fi ara wa hàn bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùúrù, nínú ìpọ́njú, nínú àìní, nínú wàhálà, 5nípa nínà, nínú túbú, nínú ìrúkèrúdò, nínú iṣẹ́ àṣekára, nínú àìsàn, nínú ìgbààwẹ̀. 6Nínú ìwà mímọ́, nínú ìmọ̀, nínú ìpamọ́ra, nínú ìṣeun, nínú Ẹ̀mí Mímọ́, nínú ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.