2 Kọrinti 6:16
2 Corinthians 6:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìrẹ́pọ̀ kín ni tẹmpili Ọlọ́run ní pẹ̀lú òrìṣà? Nítorí ẹ̀yin ní tẹmpili Ọlọ́run alààyè; gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí pé: “Èmi á gbé inú wọn, èmi o sì máa rìn láàrín wọn, èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.”
2 Corinthians 6:16 in English
2 Corinthians 6:16 · Berean Standard Bible
What agreement can exist between the temple of God and idols? For we are the temple of the living God. As God has said: “I will dwell with them and walk among them, and I will be their God, and they will be My people.”*
Context
14Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́, nítorí ìdàpọ̀ kín ni òdodo ní pẹ̀lú àìṣòdodo? Ìdàpọ̀ kín ni ìmọ́lẹ̀ sì ní pẹ̀lú òkùnkùn? 15Ìrẹ́pọ̀ kín ni Kristi ní pẹ̀lú Beliali? Tàbí ìpín wó ni ẹni tí ó gbàgbọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́? 16Ìrẹ́pọ̀ kín ni tẹmpili Ọlọ́run ní pẹ̀lú òrìṣà? Nítorí ẹ̀yin ní tẹmpili Ọlọ́run alààyè; gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí pé:
“Èmi á gbé inú wọn,
èmi o sì máa rìn láàrín wọn,
èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn,
wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.” 17Nítorí náà,
“Ẹ jáde kúrò láàrín wọn,
kí ẹ sì yá ara yín si ọ̀tọ̀,
ni Olúwa wí.
Ki ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan ohun àìmọ́;
Èmi ó sì gbà yín.” 18Àti,
“Èmi o sì jẹ́ Baba fún yín.
Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọkùnrin mi àti ọmọbìnrin mi,
ní Olúwa Olódùmarè wí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.