Native Bible

2 Corinthians 2:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Fún àwọn kan, àwa jẹ́ òórùn sí ikú, àti fún àwọn mìíràn òórùn ìyè sí ìyè. Ta ni ó ha si tọ́ fún nǹkan wọ̀nyí?

2 Corinthians 2:16 in English

2 Corinthians 2:16 · Berean Standard Bible

To the one, we are an odor of death and demise; to the other, a fragrance that brings life.* And who is qualified for such a task?

Context

14Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, ẹni tí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí wá nígbà gbogbo nínú Kristi, tí a sì ń fi òórùn dídùn ìmọ̀ rẹ̀ hàn nípa wa níbi gbogbo. 15Nítorí òórùn dídùn Kristi ni àwa jẹ́ fún Ọlọ́run, nínú àwọn tí a ń gbàlà àti nínú àwọn tí ó ń ṣègbé. 16Fún àwọn kan, àwa jẹ́ òórùn sí ikú, àti fún àwọn mìíràn òórùn ìyè sí ìyè. Ta ni ó ha si tọ́ fún nǹkan wọ̀nyí? 17Nítorí àwa kò dàbí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣòwò jẹun; ṣùgbọ́n nínú òtítọ́ inú àwa ń sọ̀rọ̀ níwájú Ọlọ́run nínú Kristi gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.