2 Kọrinti 2:13
2 Corinthians 2:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
síbẹ̀ èmi kò ní àlàáfíà lọ́kàn mi, nítorí tí èmi kò rí Titu arákùnrin mi níbẹ̀. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe dágbére fún wọn, mo si rékọjá lọ sí Makedonia.
2 Corinthians 2:13 in English
2 Corinthians 2:13 · Berean Standard Bible
I had no peace in my spirit, because I did not find my brother Titus there. So I said goodbye to them and went on to Macedonia.
Context
11Kí Satani má ba à rẹ́ wa jẹ. Nítorí àwa kò ṣe aláìmọ́ àrékérekè rẹ̀. 12Ṣùgbọ́n nígbà ti mo dé Troasi láti wàásù ìyìnrere Kristi, tí mo sì rí i wí pé Olúwa ti ṣí ìlẹ̀kùn fún mi, 13síbẹ̀ èmi kò ní àlàáfíà lọ́kàn mi, nítorí tí èmi kò rí Titu arákùnrin mi níbẹ̀. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe dágbére fún wọn, mo si rékọjá lọ sí Makedonia. 14Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, ẹni tí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí wá nígbà gbogbo nínú Kristi, tí a sì ń fi òórùn dídùn ìmọ̀ rẹ̀ hàn nípa wa níbi gbogbo. 15Nítorí òórùn dídùn Kristi ni àwa jẹ́ fún Ọlọ́run, nínú àwọn tí a ń gbàlà àti nínú àwọn tí ó ń ṣègbé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.