Native Bible

2 Corinthians 13:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí àwa ń yọ̀, nígbà ti àwa jẹ́ aláìlera, tí ẹ̀yin sì jẹ́ alágbára; èyí ni àwa sì ń gbàdúrà fún pẹ̀lú, àní pípé yín.

2 Corinthians 13:9 in English

2 Corinthians 13:9 · Berean Standard Bible

In fact, we rejoice when we are weak but you are strong, and our prayer is for your perfection.

Context

7Ǹjẹ́ àwa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, kì í ṣe nítorí kí àwa lè farahàn bí àwọn ti ó tayọ̀, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè máa ṣe èyí tí ó dára bí àwa tilẹ̀ dàbí àwọn tí a tanù. 8Nítorí àwa kò lè ṣe ohun kan lòdì sí òtítọ́, bí kò ṣe fún òtítọ́. 9Nítorí àwa ń yọ̀, nígbà ti àwa jẹ́ aláìlera, tí ẹ̀yin sì jẹ́ alágbára; èyí ni àwa sì ń gbàdúrà fún pẹ̀lú, àní pípé yín. 10Ìdí nìyí ti mo ṣe kọ̀wé àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà tí èmi kò sí lọ́dọ̀ yín, pé nígbà tí mo bá dé kí èmi má ba à lo ìkanra ní lílo àṣẹ, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa ti fi fún mí, láti mú ìdàgbàsókè, kì í ṣe láti fà yín ṣubú. 11Ní àkótán, ará ó dì gbòóṣe, ẹ ṣe àtúnṣe ọ̀nà yín, ẹ tújúká, ẹ jẹ́ onínú kan, ẹ máa wà ní àlàáfíà, Ọlọ́run ìfẹ́ àti ti àlàáfíà yóò wà pẹ̀lú yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.