2 Kọrinti 11:10
2 Corinthians 11:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó jẹ́ òtítọ́, Kristi tí ń bẹ nínú mi pé kò sí ẹni tí ó lè dá mi lẹ́kun ìṣògo yìí ni gbogbo ẹkùn Akaia.
2 Corinthians 11:10 in English
2 Corinthians 11:10 · Berean Standard Bible
As surely as the truth of Christ is in me, this boasting of mine will not be silenced in the regions of Achaia.
Context
8Èmí ń ja ìjọ mìíràn ni olè nípa gbígba ìpèsè owó ki èmi bà á lè sìn yín. 9Nígbà tí mo sì wà pẹ̀lú yín, tí mo sì ṣe aláìní, èmi kò dẹ́rù pa ẹnikẹ́ni, nítorí ohun tí mo ṣe aláìní ni àwọn ará tí ó ti Makedonia wá ti mú wá. Bẹ́ẹ̀ ni nínú ohun gbogbo mo pa ara mi mọ́ láti má ṣe jẹ́ ẹrù fún yín, èmi yóò sì pa ara mi mọ́ bẹ́ẹ̀. 10Ó jẹ́ òtítọ́, Kristi tí ń bẹ nínú mi pé kò sí ẹni tí ó lè dá mi lẹ́kun ìṣògo yìí ni gbogbo ẹkùn Akaia. 11Nítorí kín ni? Nítorí èmi kò fẹ́ràn yín ni bí? Ọlọ́run mọ̀. 12Èmi yóò tẹ̀síwájú láti máa ṣe ohun ti èmi ń ṣe láti le mú ìjákulẹ̀ bá àwọn tí wọn ń wá ọ̀nà láti bá wa dọ́gba nínú èyí ti àwa ń ṣògo lé lórí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.