Native Bible

2 Corinthians 1:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo pinnu láti bẹ̀ yín wò ní ìrìnàjò mi sí Makedonia àti láti tún bẹ̀ yín wò nígbà tí mo bá ń padà bọ̀ láti Makedonia àti wí pé kí ẹ̀yin kí ó lè rán mi láti ọ̀dọ̀ yín ní ìrìnàjò mi sí Judea.

2 Corinthians 1:16 in English

2 Corinthians 1:16 · Berean Standard Bible

I wanted to visit you on my way to Macedonia, and to return to you from Macedonia, and then to have you help me on my way to Judea.

Context

14Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin pẹ̀lú ti ní ìmọ̀ nípa wa ní apá kan, bákan náà ni ẹ ó ní ìmọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́ tí ẹ ó sì fi wá yangàn, bí àwa pẹ̀lú yóò ṣe fi yín yangàn ní ọjọ́ Jesu Olúwa. 15Nítorí mo ní ìdánilójú yìí wí pé, mo pinnu láti kọ́kọ́ bẹ̀ yín wò kí ẹ lè jẹ àǹfààní ìgbà méjì. 16Mo pinnu láti bẹ̀ yín wò ní ìrìnàjò mi sí Makedonia àti láti tún bẹ̀ yín wò nígbà tí mo bá ń padà bọ̀ láti Makedonia àti wí pé kí ẹ̀yin kí ó lè rán mi láti ọ̀dọ̀ yín ní ìrìnàjò mi sí Judea. 17Nítorí náà nígbà tí èmi ń gbèrò bẹ́ẹ̀, èmi ha ṣiyèméjì bí? Tàbí àwọn ohun tí mo pinnu, mo ha pinnu wọn gẹ́gẹ́ bí ti ará bí, pé kí ó jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ ní, bẹ́ẹ̀ ní” àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bẹ́ẹ̀ kọ́”? 18Ṣùgbọ́n bí Ọlọ́run tí jẹ́ olóòtítọ́, ọ̀rọ̀ wa fún yín kí í ṣe bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.