2 Kronika 9:21
2 Chronicles 9:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba ní ọkọ̀ tí a fi ń tajà tí àwọn ọkùnrin Hiramu ń bojútó. Ẹ̀ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ó máa ń padà, ó ń gbé wúrà àti fàdákà àti eyín erin àti ìnàkí.
2 Chronicles 9:21 in English
2 Chronicles 9:21 · Berean Standard Bible
For the king had the ships of Tarshish * that went with Hiram’s * servants, and once every three years the ships of Tarshish would arrive bearing gold, silver, ivory, apes, and peacocks.*
Context
19Kìnnìún méjìlá dúró lórí àtẹ̀gùn mẹ́ta, ọ̀kan àti ní ìhà olúkúlùkù àtẹ̀gùn kò sì sí irú rẹ̀ tí a ti ṣe rí fún ìjọba mìíràn. 20Gbogbo ohun èlò mímú ìjọba Solomoni ọba ni ó jẹ́ kìkì wúrà, àti gbogbo ohun èlò ààfin ní igbó Lebanoni ni ó jẹ́ wúrà mímọ́. Kò sì ṣí èyí tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ Solomoni. 21Ọba ní ọkọ̀ tí a fi ń tajà tí àwọn ọkùnrin Hiramu ń bojútó. Ẹ̀ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ó máa ń padà, ó ń gbé wúrà àti fàdákà àti eyín erin àti ìnàkí. 22Ọba Solomoni sì tóbi nínú ọláńlá àti ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba tí ó kù lórí ilẹ̀ ayé lọ. 23Gbogbo àwọn ọba ayé ń wá ojúrere lọ́dọ̀ Solomoni láti gbọ́n ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.