Native Bible

2 Chronicles 9:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Solomoni sì dá a lóhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyíkéyìí tí kò lè ṣe àlàyé fún.

2 Chronicles 9:2 in English

2 Chronicles 9:2 · Berean Standard Bible

And Solomon answered all her questions; nothing was too difficult for him to explain.

Context

1Nígbà tí ayaba Ṣeba gbọ́ nípa òkìkí Solomoni, ó sì wá sí Jerusalẹmu láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè tí ó le. Ó dé pẹ̀lú ẹgbẹ́ ńlá kan pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye wúrà, àti òkúta iyebíye, ó wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn rẹ̀. 2Solomoni sì dá a lóhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyíkéyìí tí kò lè ṣe àlàyé fún. 3Nígbà tí ayaba Ṣeba rí ọgbọ́n Solomoni àti pẹ̀lú ilé tí ó ti kọ́, 4oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì rẹ̀, àti ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti dídúró àwọn ìránṣẹ́ nínú aṣọ wọn, àti àwọn agbọ́tí nínú aṣọ wọn àti ẹbọ sísun tí ó ṣe ní ilé Olúwa, ó sì dá a lágara fún ìyàlẹ́nu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.