Native Bible

2 Chronicles 9:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, àti pẹ̀lú àpótí ìtìsẹ̀ wúrà kan ni a dè mọ́ ọn. Ní ìhà méjèèjì ibi ìjókòó ní ó ní ìgbọ́wọ́lé, pẹ̀lú kìnnìún tí ó dúró lẹ́bàá olúkúlùkù wọn.

2 Chronicles 9:18 in English

2 Chronicles 9:18 · Berean Standard Bible

The throne had six steps, and a footstool of gold was attached to it. There were armrests on both sides of the seat, with a lion standing beside each armrest.

Context

16Ó sì ti ṣe ọ̀ọ́dúnrún (300) kékeré ṣékélì tí a fi òlùlù wúrà, pẹ̀lú ọ̀ọ́dúnrún (300) ṣékélì wúrà nínú àpáta kọ̀ọ̀kan. Ọba sì kó wọn sínú ààfin ti ó wà ní igbó Lebanoni. 17Nígbà náà ọba sì ṣe ìtẹ́ pẹ̀lú eyín erin ńlá kan ó sì fi wúrà tó mọ́ bò ó. 18Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, àti pẹ̀lú àpótí ìtìsẹ̀ wúrà kan ni a dè mọ́ ọn. Ní ìhà méjèèjì ibi ìjókòó ní ó ní ìgbọ́wọ́lé, pẹ̀lú kìnnìún tí ó dúró lẹ́bàá olúkúlùkù wọn. 19Kìnnìún méjìlá dúró lórí àtẹ̀gùn mẹ́ta, ọ̀kan àti ní ìhà olúkúlùkù àtẹ̀gùn kò sì sí irú rẹ̀ tí a ti ṣe rí fún ìjọba mìíràn. 20Gbogbo ohun èlò mímú ìjọba Solomoni ọba ni ó jẹ́ kìkì wúrà, àti gbogbo ohun èlò ààfin ní igbó Lebanoni ni ó jẹ́ wúrà mímọ́. Kò sì ṣí èyí tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ Solomoni.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.