Native Bible

2 Chronicles 9:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

láì tí ì ka àkójọpọ̀ owó ìlú tí ó wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò àti àwọn ọlọ́jà. Àti pẹ̀lú gbogbo àwọn ọba Arabia àti àwọn baálẹ̀ ilẹ̀ náà mu wúrà àti fàdákà wá fún Solomoni.

2 Chronicles 9:14 in English

2 Chronicles 9:14 · Berean Standard Bible

not including the revenue from the merchants and traders. And all the Arabian kings and governors of the land also brought gold and silver to Solomon.

Context

12Ọba Solomoni fún ayaba Ṣeba ní gbogbo ohun tí ó béèrè fún àti ohun tí ó wù ú; ó sì fi fún un ju èyí tí ó mú wá fún un lọ. Nígbà náà ni ó lọ ó sì padà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìlú rẹ̀. 13Ìwọ̀n wúrà tí Solomoni gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà (666) tálẹ́ǹtì, 14láì tí ì ka àkójọpọ̀ owó ìlú tí ó wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò àti àwọn ọlọ́jà. Àti pẹ̀lú gbogbo àwọn ọba Arabia àti àwọn baálẹ̀ ilẹ̀ náà mu wúrà àti fàdákà wá fún Solomoni. 15Ọba Solomoni sì ṣe igba asà wúrà lílù; ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì tí a fi òlùlù wúrà sí ọ̀kánkán asà. 16Ó sì ti ṣe ọ̀ọ́dúnrún (300) kékeré ṣékélì tí a fi òlùlù wúrà, pẹ̀lú ọ̀ọ́dúnrún (300) ṣékélì wúrà nínú àpáta kọ̀ọ̀kan. Ọba sì kó wọn sínú ààfin ti ó wà ní igbó Lebanoni.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.