Native Bible

2 Chronicles 9:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọba sì lo igi algumu náà láti fi ṣe àtẹ̀gùn fún ilé Olúwa àti fún ilé ọba àti láti fi ṣe dùùrù àti ohun èlò orin olókùn fún àwọn akọrin. Kò sì ṣí irú rẹ̀ tí a ti rí rí ní ilẹ̀ Juda.

2 Chronicles 9:11 in English

2 Chronicles 9:11 · Berean Standard Bible

The king made the algum wood into steps * for the house of the LORD and for the king’s palace, and into lyres and harps for the singers. Never before had anything like them been seen in the land of Judah.)

Context

9Nígbà náà ni ó sì fún ọba ní ọgọ́fà tálẹ́ǹtì wúrà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye tùràrí, àti òkúta iyebíye. Kò sì tí ì sí irú tùràrí yí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ayaba Ṣeba fi fún ọba Solomoni. 10Àwọn ènìyàn Hiramu àti àwọn ọkùnrin Solomoni gbé wúrà wá láti Ofiri, wọ́n sì tún gbé igi algumu pẹ̀lú àti òkúta iyebíye wá. 11Ọba sì lo igi algumu náà láti fi ṣe àtẹ̀gùn fún ilé Olúwa àti fún ilé ọba àti láti fi ṣe dùùrù àti ohun èlò orin olókùn fún àwọn akọrin. Kò sì ṣí irú rẹ̀ tí a ti rí rí ní ilẹ̀ Juda. 12Ọba Solomoni fún ayaba Ṣeba ní gbogbo ohun tí ó béèrè fún àti ohun tí ó wù ú; ó sì fi fún un ju èyí tí ó mú wá fún un lọ. Nígbà náà ni ó lọ ó sì padà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìlú rẹ̀. 13Ìwọ̀n wúrà tí Solomoni gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà (666) tálẹ́ǹtì,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.