2 Kronika 7:9
2 Chronicles 7:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ kẹjọ, wọ́n sì pe ìjọ ènìyàn jọ nítorí tí wọ́n pe àpèjẹ ìyàsímímọ́ ti orí pẹpẹ fún ọjọ́ méje àti àsè náà fún ọjọ́ méje sí i.
2 Chronicles 7:9 in English
2 Chronicles 7:9 · Berean Standard Bible
On the eighth day they held a solemn assembly, for the dedication of the altar had lasted seven days, and the feast seven days more.
Context
7Solomoni sì yà àgbàlá níwájú ilé Olúwa sọ́tọ̀, níbẹ̀ sì ni ó ti ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun àti ọ̀rá ẹbọ àlàáfíà, nítorí pẹpẹ idẹ tí ó ti ṣe kò lè gba ẹbọ sísun, àti ọrẹ oúnjẹ, àti ọ̀rá náà. 8Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe àsè ní àkókò náà fún ọjọ́ méje àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú rẹ̀ àti ìjọ ènìyàn ńlá, àwọn ènìyàn láti Lebo-Hamati títí dé odò Ejibiti. 9Ní ọjọ́ kẹjọ, wọ́n sì pe ìjọ ènìyàn jọ nítorí tí wọ́n pe àpèjẹ ìyàsímímọ́ ti orí pẹpẹ fún ọjọ́ méje àti àsè náà fún ọjọ́ méje sí i. 10Ní ọjọ́ kẹtàlélógún tí oṣù keje, ó sì rán àwọn ènìyàn padà sí ilé wọn, pẹ̀lú ayọ̀ àti ìdùnnú nínú wọn fún ohun rere tí Olúwa ti ṣe fún Dafidi àti Solomoni, àti fún àwọn ènìyàn Israẹli. 11Nígbà tí Solomoni ti parí ilé Olúwa àti ibi ilé ọba, nígbà tí ó sì ti ṣe àṣeyọrí láti gbé jáde gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe nínú ilé Olúwa àti nínú ilé òun tìkára rẹ̀,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.