Native Bible

2 Chronicles 6:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Níbẹ̀ ni èmi sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa sí, nínú èyí ti májẹ̀mú ti Olúwa bá àwọn Israẹli ènìyàn mi dá wà.”

2 Chronicles 6:11 in English

2 Chronicles 6:11 · Berean Standard Bible

And there I have provided a place for the ark, which contains the covenant of the LORD that He made with the children of Israel.”

Context

9Ṣùgbọ́n síbẹ̀, ìwọ kọ́ ni yóò kọ́ tẹmpili náà, bí kò ṣe ọmọ rẹ, ẹni tí o jẹ́ ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ rẹ: òun ni yóò kọ́ tẹmpili fún orúkọ mi.’ 10“Olúwa sì ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Èmi ti dìde ní ipò Dafidi baba mi, a sì gbé mi ka ìtẹ́ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣe ìlérí, èmi sì ti kọ́ tẹmpili fún orúkọ Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. 11Níbẹ̀ ni èmi sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa sí, nínú èyí ti májẹ̀mú ti Olúwa bá àwọn Israẹli ènìyàn mi dá wà.” 12Nígbà náà ni Solomoni dúró níwájú pẹpẹ Olúwa, ní iwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì. 13Solomoni ṣe àga idẹ kan tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gíga, a gbé e sí àárín àgbàlá ti òde. Ó sì dúró ní orí rẹ̀, àti pé ó kúnlẹ̀ lórí eékún rẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí òkè ọ̀run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.