2 Kronika 5:2
2 Chronicles 5:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Solomoni pe àwọn àgbàgbà Israẹli jọ sí Jerusalẹmu, gbogbo àwọn olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan àti àwọn olóyè àwọn ìdílé Israẹli, kí wọn kí ó gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa gòkè wá láti Sioni ìlú Dafidi.
2 Chronicles 5:2 in English
2 Chronicles 5:2 · Berean Standard Bible
At that time Solomon assembled in Jerusalem the elders of Israel—all the tribal heads and family leaders of the Israelites—to bring up the ark of the covenant of the LORD from Zion, the City of David.
Context
1Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ tí Solomoni ti ṣe fún tẹmpili Olúwa ti parí, ó kó gbogbo àwọn nǹkan tí Dafidi baba rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀: wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò ọ̀ṣọ́, ó sì fi wọ́n sínú ìṣúra ilé Ọlọ́run. 2Nígbà náà ni Solomoni pe àwọn àgbàgbà Israẹli jọ sí Jerusalẹmu, gbogbo àwọn olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan àti àwọn olóyè àwọn ìdílé Israẹli, kí wọn kí ó gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa gòkè wá láti Sioni ìlú Dafidi. 3Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli péjọ sí ọ̀dọ̀ ọba ní àkókò àjọ àgọ́. 4Gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli sì wá, àwọn ọmọ Lefi gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.