Native Bible

2 Chronicles 4:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó ṣe àgbàlá àwọn àlùfáà àti ààfin ńlá àti àwọn ìlẹ̀kùn fún ààfin, ó sì tẹ́ àwọn ìlẹ̀kùn náà pẹ̀lú idẹ.

2 Chronicles 4:9 in English

2 Chronicles 4:9 · Berean Standard Bible

He made the courtyard of the priests and the large court with its doors, and he overlaid the doors with bronze.

Context

7Ó ṣe ìgbé fìtílà dúró mẹ́wàá ti wúrà gẹ́gẹ́ bí èyí tí a yàn fún wọn. A sì gbé wọn kalẹ̀ sínú ilé Olúwa márùn un ní ìhà gúúsù àti márùn-ún ní ìhà àríwá. 8Ó ṣé tábìlì mẹ́wàá, ó sì gbé wọn sí inú ilé Olúwa, márùn un ní gúúsù àti márùn-ún ní ìhà àríwá. Ó ṣé ọgọ́rùn-ún ọpọ́n ìbùwọ́n wúrà. 9Ó ṣe àgbàlá àwọn àlùfáà àti ààfin ńlá àti àwọn ìlẹ̀kùn fún ààfin, ó sì tẹ́ àwọn ìlẹ̀kùn náà pẹ̀lú idẹ. 10Ó gbé Òkun náà ka orí ìhà gúúsù ní ẹ̀bá igun gúúsù àríwá. 11Huramu ṣe àwọn ìkòkò pẹ̀lú, àti ọkọ́ àti àwọn ọpọ́n ìbùwọ́n. Bẹ́ẹ̀ ni Huramu parí iṣẹ́ tí ó ti dáwọ́lé fún ọba Solomoni ní ilé Ọlọ́run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.