Native Bible

2 Chronicles 4:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó ṣe ọpọ́n mẹ́wàá fún fífọ nǹkan, ó sì gbé márùn-ún ka ìhà gúúsù àti márùn-ún ní àríwá. Nínú wọn ni ó ti ń fọ àwọn nǹkan tí wọ́n ń lò fún ẹbọ sísun ṣùgbọ́n, àwọn àlùfáà ní ó ń lo Òkun fún fífọ nǹkan.

2 Chronicles 4:6 in English

2 Chronicles 4:6 · Berean Standard Bible

He also made ten basins for washing and placed five on the south side and five on the north. The parts of the burnt offering were rinsed in them, but the priests used the Sea for washing.

Context

4Okùn náà dúró lórí akọ màlúù méjìlá, mẹ́ta kọjú sí àríwá, mẹ́ta kọjú sí ìwọ̀-oòrùn, mẹ́ta kọjú sí gúúsù mẹ́ta kọjú sí ìlà-oòrùn. Òkun náà sì sinmi lórí wọn àti gbogbo ìhà ẹ̀yìn wọn sì wà ní apá àárín. 5Ó nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ sì dàbí etí ife ìmumi, bí i ìtànná lílì ó sì dá ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) bati dúró. 6Ó ṣe ọpọ́n mẹ́wàá fún fífọ nǹkan, ó sì gbé márùn-ún ka ìhà gúúsù àti márùn-ún ní àríwá. Nínú wọn ni ó ti ń fọ àwọn nǹkan tí wọ́n ń lò fún ẹbọ sísun ṣùgbọ́n, àwọn àlùfáà ní ó ń lo Òkun fún fífọ nǹkan. 7Ó ṣe ìgbé fìtílà dúró mẹ́wàá ti wúrà gẹ́gẹ́ bí èyí tí a yàn fún wọn. A sì gbé wọn kalẹ̀ sínú ilé Olúwa márùn un ní ìhà gúúsù àti márùn-ún ní ìhà àríwá. 8Ó ṣé tábìlì mẹ́wàá, ó sì gbé wọn sí inú ilé Olúwa, márùn un ní gúúsù àti márùn-ún ní ìhà àríwá. Ó ṣé ọgọ́rùn-ún ọpọ́n ìbùwọ́n wúrà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.