Native Bible

2 Chronicles 4:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

àwọn ọ̀pá fìtílà tí a fi ojúlówó wúrà ṣe pẹ̀lú fìtílà wọn kí wọn lè máa jó gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ní iwájú ibi mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí a ṣe fi lélẹ̀;

2 Chronicles 4:20 in English

2 Chronicles 4:20 · Berean Standard Bible

the lampstands of pure gold and their lamps, to burn in front of the inner sanctuary as prescribed;

Context

18Gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí Solomoni ṣe ní iye lórí púpọ̀ tí a kò le mọ ìwọ̀n iye idẹ tí ó wọ́n. 19Solomoni pẹ̀lú ṣe gbogbo ohun èlò tí ó wà ní ilé Ọlọ́run: pẹpẹ wúrà tábìlì èyí tí àkàrà ìfihàn wà lórí rẹ̀; 20àwọn ọ̀pá fìtílà tí a fi ojúlówó wúrà ṣe pẹ̀lú fìtílà wọn kí wọn lè máa jó gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ní iwájú ibi mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí a ṣe fi lélẹ̀; 21pẹ̀lú ìtànná wúrà àti fìtílà àti ẹ̀mú ni ó jẹ́ kìkìdá wúrà tí ó gbópọn; 22pẹ̀lú ọ̀pá fìtílà, àti àwokòtò àti ṣíbí àti àwokòtò tùràrí àti àwọn ìlẹ̀kùn wúrà ti inú tẹmpili, àwọn ìlẹ̀kùn ibi mímọ́ sí Ibi Mímọ́ Jùlọ àti àwọn ìlẹ̀kùn à bá wọ inú gbọ̀ngàn ńlá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.