Native Bible

2 Chronicles 36:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, kò sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jeremiah wòlíì ẹni tí ó sọ̀rọ̀ Olúwa.

2 Chronicles 36:12 in English

2 Chronicles 36:12 · Berean Standard Bible

And he did evil in the sight of the LORD his God and did not humble himself before Jeremiah the prophet, who spoke for the LORD.

Context

10Ní àkókò òjò, ọba Nebukadnessari ránṣẹ́ sí i ó sì mú un wá sí Babeli, pẹ̀lú ohun èlò dáradára láti ilé Olúwa, ó sì mú arákùnrin Jehoiakini, Sedekiah, jẹ ọba lórí Juda àti Jerusalẹmu. 11Sedekiah jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlá. 12Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, kò sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jeremiah wòlíì ẹni tí ó sọ̀rọ̀ Olúwa. 13Ó sì tún ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Nebukadnessari pẹ̀lú, ẹni tí ó mú kí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra. Ó sì di ọlọ́run líle, ó sì mú ọkàn rẹ̀ le láti má lè yípadà sí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. 14Síwájú sí i gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn sì di ẹni tí ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi, pẹ̀lú gbogbo ìríra àwọn orílẹ̀-èdè wọ́n sì sọ ilé Olúwa di èérí, tí ó ti yà sí mímọ́ ní Jerusalẹmu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.