2 Kronika 35:23
2 Chronicles 35:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Tafàtafà sì ta ọfà sí ọba Josiah, ó sì sọ fún àwọn ìjòyè pé, “Ẹ gbé mi kúrò, èmi ti gba ọgbẹ́ gidigidi.”
2 Chronicles 35:23 in English
2 Chronicles 35:23 · Berean Standard Bible
There the archers shot King Josiah, who said to his servants, “Take me away, for I am badly wounded!”
Context
21Ṣùgbọ́n Neko rán ìránṣẹ́ sí i wí pé, “Ìjà wo ni ó ń bẹ láàrín èmi àti ìwọ, ọba Juda? Kì í ṣe ìwọ ni èmi tọ̀ wá ní àkókò yìí, ṣùgbọ́n, ilé pẹ̀lú èyí ti mo bá níjà. Ọlọ́run ti sọ fún mi láti yára àti láti dúró nípa ṣíṣe ìdènà Ọlọ́run, ẹni tí ó wà pẹ̀lú mi, kí òun má bá a pa ọ́ run.” 22Josiah, kò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó pa ara rẹ̀ dà kí ó le bá a jà, kó sì fi etí sí ọ̀rọ̀ Neko láti ẹnu Ọlọ́run wá, ó sì wá jagun ní àfonífojì Megido. 23Tafàtafà sì ta ọfà sí ọba Josiah, ó sì sọ fún àwọn ìjòyè pé, “Ẹ gbé mi kúrò, èmi ti gba ọgbẹ́ gidigidi.” 24Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbé e jáde kúrò nínú kẹ̀kẹ́ náà, wọ́n sì gbé e sínú kẹ̀kẹ́ mìíràn, wọ́n sì gbé e wá sí Jerusalẹmu, níbi tí ó ti kú, wọ́n sì sin ín sínú ọ̀kan nínú àwọn ibojì àwọn baba rẹ̀, gbogbo Juda àti gbogbo Jerusalẹmu sì ṣọ̀fọ̀ Josiah. 25Jeremiah sì pohùnréré ẹkún fún Josiah, gbogbo àwọn akọrin ọkùnrin àti gbogbo àwọn akọrin obìnrin sì ń sọ ti Josiah nínú orin ẹkún wọn ní Israẹli títí di òní. Èyí sì di àṣà ní Jerusalẹmu, a sì kọ ọ́ sínú àwọn orin ẹkún.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.