Native Bible

2 Chronicles 35:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn gbogbo èyí nígbà tí Josiah ti tún ilẹ̀ náà ṣetán, Neko ọba Ejibiti gòkè lọ láti bá Karkemiṣi jà lórí odo Eufurate, Josiah sì jáde lọ láti pàdé rẹ̀ ní ibi ìjà.

2 Chronicles 35:20 in English

2 Chronicles 35:20 · Berean Standard Bible

After all this, when Josiah had set the temple in order, Neco king of Egypt marched up to fight at Carchemish by the Euphrates, and Josiah went out to confront him.

Context

18Àjọ ìrékọjá náà kò sì tí ì sí èyí tí ó dàbí i rẹ̀ ní Israẹli títí dé ọjọ́ wòlíì Samuẹli, kò sì sí ọ̀kan lára àwọn ọba Israẹli tí ó pa irú àjọ ìrékọjá bẹ́ẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Josiah ti ṣe, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àwọn ọmọ Lefi àti gbogbo àwọn Juda àti Israẹli tí ó wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu. 19Àjọ ìrékọjá yìí ni a ṣe ìrántí ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Josiah. 20Lẹ́yìn gbogbo èyí nígbà tí Josiah ti tún ilẹ̀ náà ṣetán, Neko ọba Ejibiti gòkè lọ láti bá Karkemiṣi jà lórí odo Eufurate, Josiah sì jáde lọ láti pàdé rẹ̀ ní ibi ìjà. 21Ṣùgbọ́n Neko rán ìránṣẹ́ sí i wí pé, “Ìjà wo ni ó ń bẹ láàrín èmi àti ìwọ, ọba Juda? Kì í ṣe ìwọ ni èmi tọ̀ wá ní àkókò yìí, ṣùgbọ́n, ilé pẹ̀lú èyí ti mo bá níjà. Ọlọ́run ti sọ fún mi láti yára àti láti dúró nípa ṣíṣe ìdènà Ọlọ́run, ẹni tí ó wà pẹ̀lú mi, kí òun má bá a pa ọ́ run.” 22Josiah, kò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó pa ara rẹ̀ dà kí ó le bá a jà, kó sì fi etí sí ọ̀rọ̀ Neko láti ẹnu Ọlọ́run wá, ó sì wá jagun ní àfonífojì Megido.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.