2 Kronika 34:6
2 Chronicles 34:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ìlú Manase, Efraimu àti Simeoni, àní títí ó fi dé Naftali, àti nínú àwọn, ó tú ilé wọn yíkákiri.
2 Chronicles 34:6 in English
2 Chronicles 34:6 · Berean Standard Bible
Josiah did the same in the cities of Manasseh, Ephraim, and Simeon, as far as Naphtali, and in the ruins * around them.
Context
4Lábẹ́ àpẹẹrẹ àwọn pẹpẹ Baali ni a yí lulẹ̀, ó sì fọ́ àwọn ère sí wẹ́wẹ́, ó run àwọn pẹpẹ tí ó wà lórí rẹ̀, wọ́n sì fọ́ túútúú, àwọn ère Aṣerah àti àwọn òrìṣà. Èyí tí ó fọ́ wọn sì lúúlúú, ó sì gbọ̀n wọ́n sí orí isà òkú àti àwọn tí ó ń rú ẹbọ sí wọn. 5Ó sì sun àwọn egungun àwọn àlùfáà lórí pẹpẹ wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ó sì wẹ Juda àti Jerusalẹmu mọ́. 6Ní ìlú Manase, Efraimu àti Simeoni, àní títí ó fi dé Naftali, àti nínú àwọn, ó tú ilé wọn yíkákiri. 7Ó sì wó pẹpẹ àti ère Aṣerah lulẹ̀ àti àwọn ère yíyá àti àwọn òrìṣà, ó sì gùn ó sì ti ké gbogbo àwọn ère orí pẹpẹ lulẹ̀ ní gbogbo àyíká Israẹli. Lẹ́yìn náà ó padà sí Jerusalẹmu. 8Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Josiah ni a ti wẹ ilẹ̀ náà mọ́ àti ilé Olúwa, ó sì rán Ṣafani ọmọ Asalia àti Maaseiah olórí ìlú náà, pẹ̀lú Joah, ọmọ Joahasi, akọ̀wé, láti tún ilé Olúwa Ọlọ́run ṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.