2 Kronika 34:3
2 Chronicles 34:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀, nígbà tí ó sì wà ní ọ̀dọ́mọdé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá ojú Ọlọ́run baba Dafidi. Ní ọdún kejìlá. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ Juda àti Jerusalẹmu mọ́ kúrò ní ibi gíga rẹ̀, ère òrìṣà Aṣerah, àti ère yíyá àti ère dídà.
2 Chronicles 34:3 in English
2 Chronicles 34:3 · Berean Standard Bible
In the eighth year of his reign, while he was still young, Josiah began to seek the God of his father David, and in the twelfth year he began to cleanse Judah and Jerusalem of the high places, the Asherah poles, the carved idols, and the cast images.
Context
1Josiah sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́jọ nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì dí ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n. 2Ó sì ṣe ohun tí ó dára ní ojú Olúwa, ó sì rìn ọ̀nà baba rẹ̀ Dafidi, kò sì yà sí ọwọ́ ọ̀tún tàbí òsì. 3Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀, nígbà tí ó sì wà ní ọ̀dọ́mọdé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá ojú Ọlọ́run baba Dafidi. Ní ọdún kejìlá. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ Juda àti Jerusalẹmu mọ́ kúrò ní ibi gíga rẹ̀, ère òrìṣà Aṣerah, àti ère yíyá àti ère dídà. 4Lábẹ́ àpẹẹrẹ àwọn pẹpẹ Baali ni a yí lulẹ̀, ó sì fọ́ àwọn ère sí wẹ́wẹ́, ó run àwọn pẹpẹ tí ó wà lórí rẹ̀, wọ́n sì fọ́ túútúú, àwọn ère Aṣerah àti àwọn òrìṣà. Èyí tí ó fọ́ wọn sì lúúlúú, ó sì gbọ̀n wọ́n sí orí isà òkú àti àwọn tí ó ń rú ẹbọ sí wọn. 5Ó sì sun àwọn egungun àwọn àlùfáà lórí pẹpẹ wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ó sì wẹ Juda àti Jerusalẹmu mọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.